Ibibo Ọsun: Ẹgbẹ APC jawe olubori ninu idibo sipo Kansẹlọ

Oríṣun àwòrán, AFP
Ajọ olominira to n se kokaari eto idibo ni ipinlẹ Osun, OSIEC ti kede awọn oludije ọ̀rìnlélọ̀dúnrún ó lé mẹ́sàn-án lati ẹgbẹ oselu APC gẹgẹbi ẹni to jawe olubori ninu idibo sipo Kansẹlọ ni ipinlẹ Ọsun.
Adari ajọ OSIEC, Ọgbẹni Sẹgun Ọladitan nigba ti wọn fi esi idibo na s'ita fun awọn oniroyin ni ilu Osogbo, sọ wi pe Mejiladinirinwo ninu awọn oludije naa ni ko si ẹni ti o ba wọn figagbaga.

Oríṣun àwòrán, OLU ALEBIOSU
Ọladitan sọ wipe Mejidinlaadoje ninu awọn oludije ti wọn pada si ipo wọn ni o wa lati agbegbe ẹkun idibo aringbungbun, nigbati mẹtadinlọgọfa wa lati iwọ-oorun ipinlẹ Ọṣun, ti awọn mẹtalelaadọrin yooku si wa lati ẹkun idibo ila-oorun ipinlẹ naa.
Lẹyin ti o se ikede yi, a wa fun awọn ti o jawe olubori sipo Kansẹlọ naa ni iwe ijẹrisi-ipadasi ẹnu isẹ (Certificate of Return).

Oríṣun àwòrán, OLU ALEBIOSU
Alaga ajọ OSIEC naa wa fikun wi pe, awọn kansẹlọ tuntun naa yoo maa lo eto isakoso ti ile-igbimọ asofin, ti awọn kansẹlọ naa yoo si yan alaga laaarin ara wọn.





















