Ọ̀ṣun 2018: Nítorí ipò Gómìnà, àwọn ọ̀dọ́ Ìwó ṣè'wọ́de

Àwọn ọ̀dọ́ Ọ̀ṣun

Oríṣun àwòrán, Funmi Sodiq

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọ̀dọ́ Ọ̀ṣun
Published

Nibayii awọn ọdọ ilu Iwo ti ṣe iwọde lati pe fun yiyan gomina to kan lati ilu Iwo.Awọn ọdọ ilu Iwo fọn ka si igboro ilu naa lati tako ohun ti won pe ni iyanjẹ oṣelu fun ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Ọṣun.

Awọn ọdọ naa labẹ aṣia ẹgbẹ to nja fun imuṣẹ yiyan ọmọ Iwo sipo gomina, 'Concerned Iwoland Youth For Actualisation Iwolokan Agenda' rin lati gbọngan ilu Iwo titi de ọja Odo Ori market pẹlu oniruuru patako alakọle ti won kọ ẹhonu wọn si.

Àwọn ọ̀dọ́ Ọ̀ṣun

Oríṣun àwòrán, Funmi Sodiq

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọ̀dọ́ Ọ̀ṣun

Agbenuso fun ẹgbẹ́ naa, Akin Ashifat salaye fun awọn oníròyìn pe ọpọ igba ni wọn ti yan ilu Iwo jẹ lainaani ipa ribiri to ko lori idagbasoke iṣejọba tiwa-n-tiwa nipinlẹ Ọṣun.Wọn ni 'ẹkun apapọ Iwo nikan ni ko lee tọka si akanṣe iṣẹ kan ṣoṣo to jẹ ti ijọba apapọ eleyii ti o n ṣe akoba fun idagbasoke eto ọrọ aje ati igbayegbadun araalu nibẹ. Opopona wa ko dara, kosi omi ẹrọ fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin.'

Àwọn ọ̀dọ́ Ọ̀ṣun

Oríṣun àwòrán, Funmi Sodiq

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọ̀dọ́ Ọ̀ṣun

"Gbogbo awọn ijọba ti o n jẹ niIpinlẹ Ọṣun ko si ṣe ohunkohun lati tu awọn eeyan ilu Iwo lara."Laipẹ yii ni ọba ilu iwo, Ọba Rasheed Akanbi bẹ olu ileeṣẹ APC wo nilu Oṣogbo lati kin ipe fun yiyan ọmọ ilu Iwo gẹgẹ bi oludije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu naa.Lara awọn ọmọ ilu Iwo to fẹ du ipo gomina ipinlẹ Ọṣun nibi idibo gomina ti yoo waye loṣu kẹsan ọdun yii ni Najeem Salaam to jẹ olori ile aṣofin ipinlẹ naa ati Moshood Adeoti to jẹ akọwe ijọba.