Ekiti Election: Kolapo Olusola gbé Inec lọ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Oríṣun àwòrán, @elekaolusola
Published
Oludibo ni ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kolapo Olusola ti kọ iwe ipẹjọ mọ Ajọ Eleto Idibo lori pe wọn kede ẹgbẹ oselu APC gẹgẹbi ẹni to jawe olubori ninu idibo si ipo gomina to waye ni Osu to kọja.
Ninu iwe ipẹjọ to fi lede, Olusola ni ki Ajọ Eleto Idibo, Inec o kede wipe oun lo jawe olubori ninu idibo to waye naa.
Olusọla ninu ọrọ rẹ sọ wi pe Ajọ Inec se magomago, ati wipe wọn ji esi idibo gbe ni awọn agbeegbe kan lasiko idibo naa.
Inec kede Kayode Fayemi ti ẹgbẹ oselu APC gẹgẹbi ẹni to jawe olubori ninu idibo to waye ni Osu Kẹjo, ọdun 2018.






















