Osun Election 2018: INEC korò ojú sí bí wọ́n ṣe fìyà jẹ òṣìṣẹ́ tó ya èsì ìbò

Àkọlé fídíò, Isọkusọ ní INEC sọ lórí ìdìbò Osun
Published
Awọn osisẹ eleto idibo

Àjọ elétò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC, ti fèsì lórí òṣìṣẹ́ rẹ̀ kan tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó ya ìwé èsì ìbò lásìkò tí wọ́n n kéde àbájáde èsì ìdìbò sípò gómìnà tó wáyé l'Ọṣun.

Nínú ìkéde kan tí àjọ nàá fi síta l'ójú òpó Twitter ni INEC ti ṣàlàyé pé àṣẹ tí wọ́n pa fún òṣìṣẹ́ nàá, Mutiu Salawu, ló tẹ̀lé, kìíṣe ọ̀nà láti ba èsì ìdìbò jẹ́ tàbí bo ẹnikẹ́ni l'ásìrí.

INEC ní àsìṣe ni ẹgbẹ̀rún kan ìbò tí wọ́n fi kún ìbò ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, ní wọ́ọ̀dù kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Ayédáadé.

Àti pé àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tí aṣojú ẹgbẹ́ PDP tọ́ka sí ìyàtọ̀ tó wà láàrin èsì ìdìbò tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ògiri àti èyì tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọtunde Adeagbo tó kéde èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ nàá kéde fihàn pé àsìṣe ni ẹgbẹ̀rún kan ìbò nàá, àti pé èyí tí INEC kéde ni ojúlówó.

'Kò sí ìdọ́gba nínú ìgbésẹ àjọ INEC lórí ìdìbò ní Nàìjíríà'

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lo kọkọ kéde pé àwọn kọ ìkéde àtúndì ìbò INEC àti pé ìkéde yìí á ṣàkóbá fún ìṣejọba Àwa-ara-wa.

Lẹyin wọn ni awọn amofin kan naa ni Naijiria ti n se agbeyẹwo igbese naa ti wọn si ti n wi iriwisi otọtọ.

Bi awọn kan ti se n sọ pe igbese INEC ba ofin mu ni awọn kan n sọ pe isọkusọ ni INEC n sọ.

Kayode Ajulo to jẹ amofin nilu Abuja so pe ''ofin ilẹ wa sagba ofin ti INEC n lo. Ti a ba si ti ri ẹni ti o ni ibo julọ ninu esi idibo,ki la tun fẹ se atundi ibo fun?''

Aworan Kayode Ajulọ

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kayode Ajulo

Àkọlé àwòrán, Ejo lọwọ ninu pẹlu igbesẹ INEC lọsun

O tesiwaju pe INEC ti fihan pe ohun ti gbadode pẹlu bi ko ti se kede oludije ẹgbẹ oselu PDP gẹgẹ bi ẹni ti o jaweolubori ninu idibo Gomina ipinlẹ Osun.

Bakanna ni Amofin Adebayo Solihu nilu Ibadan tapa si ohun ti INEC se

Aworan Solihu Adebayo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adebayo Solihu

Àkọlé àwòrán, Ile ẹjọ ti saaju dajo lori oun to sẹlẹ ni Osun

O ni iru nnkan to sẹlẹ losun tiwaye ri ni ipinlẹ Edo nibi ti ile ẹjọ ti so pe ''ibo ti wọn ba ti fagile ko si lara awọn ibo ti wọn yoo ka lati fi mọ ẹni to ba jaweolubori.''

''INEC kan se ohun to wu wọn ni pẹlu bi wọn ko se kede Adeleke gẹgẹ bi ẹni to fakọyọ''

Kini abala ofin ti Inec tele.

Abala ofin ti INEC fi kin igbese fifagile idibo to waye ni Kogi lẹyin ni eleyi to so pe ''ti iye awọn oludibo to forukọ silẹ lagbegbe ti wọn ti fagile idibo ba poju iye ibo to wa laarin ẹni to lewaju ati ẹni to tele,INEC le fagile idibo naa''

Loju opo Twitter wọn INEC fi alaye idi ti awọn fi fagile idibo to waye ni awọn aye idibo kan tio wọn si ni ki atundi ibo waye nibẹ.

Ọjọ ketadinlọgbọn osuyi ni atundi ibo yoo waye ni ibudo idibo meje nibi ti ibo eeyan ẹgbẹrun mẹta le die yoo se atọna ẹni ti yoo dipo Gomina mu ni ipinlẹ Osun.

Amofin Suleiman Abaya ati Ike Chijioke ni igbese ti INEC gbe wa ni ibamu pẹlu ofin.

''Ni ipinlẹ Osun,kii se gbogbo oludibo lo dibotan.Fun idi eyi,wọn ko le kede enikẹni gege bi ẹni to fakoyo.''

Amọ amofin Suleiman Abaya ni ''sugbọn'' to wa ninu ofin yi ni wi pe INEC gbọdi fidi ọrọ mulẹ pe aisedede wayẹ ninu idibo lawọn agbegbe naa.

''Won gbọdọ fidi rẹ mule wi pe aisedede waye lawọn aaye ti wọn ti fagile ibo yi ti awọn ounwoye eto idibo si gbodọ jẹ ri si wi pe aisede waye''

Inec ko se dọgbadọgba pẹlu igbese rẹ

Okan lara awọn akawe ti awọn amofin gẹgẹ bi Kayode Ajulo se lati toka si wipe INEC ko se deede ninu isakoso idibo to waye ni ti idibo atundi sipo asoju to waye ni ẹkun idibo Lokoja Kogi ni ipinlẹ Kogi.

Gẹgẹ bi o ti se salaye''INEC ko tẹle ofin rẹ ni Kogi nitori pe ẹgbẹ oselu APC ni ẹni to jawe olubori ti wa.''

Ninu ibo atundi sipo asofin labẹ ẹkun Lokoja Kogi to waye ni osu kẹjọ ọdun yi, nise ni ẹgbẹ oselu PDP ADC ati SDP tapa si ikede INEC pe ẹgbẹ APC lo pegede ninu idibo to waye nibẹ.

Awọn osisẹ eleto idibo

Akosilẹ fi han wi pe Ọjọgbọn Rotimi Ajayi to jẹ alamojuto ẹto idibo to waye lagbegbe naa ni Haruna Isa ẹgbẹ APC lo fakọyọ pẹlu ibo 26,800 nigba ti akẹgbẹ rẹ Bashir Abubakar ni ibo 14,845.

Iyatọ ibo to wa laarin awọn mejeji jẹ 12,015 nigba ti iye ibo ti INEC fagille lawọn aye kan jẹ 19,960.

19,960 yi kere si 51,669 to jẹ iye awọn to forukọsilẹ lati dibo ni awọn ijọba ibile meji ti aisedede ti waye ninu ibo wọn.

Nigba ti BBC kan si ajọ INEC lori aisedede yi, Oludari ipolongo ati ẹkọ oludibo ni ajọ Inec, Ọgbẹni Oluwole Osaze-Uzzi ni awọn ko le sọrọ lori isẹlẹ idibo Kogi nitori pe ọrọ naa wa ni iwaju ile ẹjọ

Ẹgbẹ PDP kò faramọ ìkede INEC lori àtúndì ìbò Ọṣun

Wọn fi lede sori ikanni twitter wọn ni @oficialpdpnigeria pe àwọn kọ èsì ìdìbò naa patapata.

Egbẹ oṣelu PDP fẹsun kan àwọn alatako pe wọn fẹ yi èrò awọn ara ilu pada ni lẹyin to ti hande pe wọn ti padanu.

Ati pe ikede ajọ eleto idibo INEC maa ṣakoba fun idagbasoke iṣejọba tiwa n tiwa ni Naijiria èyí to dàbí olè jíjà ẹ̀tọ́ àwọn ara Ọṣun.

PDP fi lede lori ikanni wọn @officialPDPNigeria pe ikede INEC yii kò ba ilana ofin Naijiria mu.

Ṣaaju ni Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ti ipinlẹ Ọṣun, Oloye Soji Adagunodo ti ba àwọn oniroyin sọrọ pé awọn ko ni gba esi idibo gomina to waye ni ọjọ Satide.

O ni èsì ti INEC fẹ kéde ba ni magomago ninu, PDP kò ni gba èsì naa rara.

Adagunodo ni bí o tilẹ jẹ pe awọn jawe olubori ninu idibo gomina naa pẹlu oodunrun ibo, àwọn kò ní gba èsì ìdìbò naa nitori awọn magomago to waye ni awọn ijọba ibilẹ kọọkan.

Ọpọlọpọ awọn eniyan lo ti ṣe iṣiro ìbò naa bi ajọ INEC Link ṣe n kaa sita.

Lojo kejilelogun, osu kesan an ni eto idibo naa waye.

Titi di asiko ti o n ba awọn oniroyin sọrọ yii, ajọ eleto idibo INEC ko tii kede ẹni to jawe olubori ninu idibo ipinlẹ Ọṣun naa.

Bakan naa lo sọrọ lori ọkunrin ti wọn mu pe o ṣiṣe ibi ni ayédáadé.