Fayemi: Kò sáàyè fún àwọn ọlọ́kadà to ń fi ọ̀kadà dáràn ní ìpínlẹ̀ Ekiti

Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, @kfayemi

Àkọlé àwòrán, Fayẹmi ni ìbárẹ́pọ̀ àlááfíà ni ìjọba ń lé láàárín àwọn akérò ní ìpínlẹ̀ náà
Published

Gomina ipinlẹ Ekiti ti fi ọkan awọn ọlọkada nipinlẹ naa balẹ pe ko si ohun ti yoo mu oun fofin de iṣẹ wọn nipinlẹ ọhun.

O ni ohun ti yoo jẹ oun logun ko ju ibarẹpọ alaafia laarin awọn ẹgbẹ awakọ ero gbogbo to wa nipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ'sa o ni bi awọn ọlọkada ba sọ ara wọn di irinṣẹ iwa ọdaran, ijọba ko ni fi oju rere wowọn rara.

Ninu atjade ti amugbalẹgbẹ lori ọrọ iroyin fun igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti, Odunayo Ogunmọla fi sita lorukọ gomina Fayẹmi, iroyin ti n kaakiri pẹlu bi wọn ṣe n ba awọn iwa ọdaran bii jija baagi gba, yiyọ owo lapo alapo, ati dida awọn onibara wọn lọna lẹyin ti wọn ba gba owo ni banki lọwọ awọn ọlọkada kan nipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì igi tó wà ní àyíká rẹ bí?

O ni eyi ku diẹ kaato ti ijọba ko si ni ṣai gbe igbesẹ to ba ts lori wọn.