Iyalode Ibadan: Bí gbogbo ètò ṣe lọ rèè níbi ìsìnkú
Published
Aminat Abiodun ti bẹrẹ si ni i gun akasọ oye láti l'ọdun 1971.
Àkọlé àwòrán, Báakú làá dère ènìyàn ò suwọ̀n láàyè, ẹyẹ ikẹyin rèé fúnIyálode Ibadan tó dolóògbé lánáà
Àkọlé àwòrán, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Abiola Ajimọbi náà dé bi òkú Ìyálode Ibadan, Gomina àti àwọn èèkàn nínú ìgbìmọ aláṣẹ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló jọ kọ́wọ́ọ̀ rìn lọ sibi ayẹyẹ ìsìkú náà
Àkọlé àwòrán, Ètò ìsìkú Iyálode ti bẹ̀rẹ̀ ní berewu, gbogbo ètò ìkẹyin ti wọn ṣe fún òkú ní ìlànà mùsùlùmí ni wọn ti gbése báyìí
Àkọlé àwòrán, Gbogbo àwọn olóyè tó fi mọ Olubadan ló péjú sibi ìsìnkú, ọ̀p's àti Ade Olúbadan to dúro yìí túmọ si pé oríade wà níkàlẹ
Àkọlé àwòrán, Ẹyẹ ìkẹyin rèé fún Iyalode Ibadan tó ti bẹrẹ si ni i gun akasọ oye láti l'ọdun 1971.
Àkọlé àwòrán, Gbogbo ọmọ bíbí ìl.ú Ibadan nílé àti lẹ̀yìn odi ló wà níbi ìsìnkú náà, tó bẹ tí gbàgede ọgbà OSBC tí wọn ń lo,ko gba ẹsẹ mọ
Àkọlé àwòrán, Awọn ààfáà náà ò gbẹ́yìn nibi ìsìkú Aminat Abiodun, Iyalode Ibadan
Àkọlé àwòrán, Awọn èèkan àti alejo pataki míran náà tún wà níbí ayẹyẹ ìsìnkú náà
Àkọlé àwòrán, Aṣọ ẹlẹgbẹ́ jẹgbẹ́ náà lọ́ràn àwọn alejo to péjú níbi isinku iyalode