Woli Kasali: Angẹli mi ni orékelẹ́wà Dọlapo Awoṣika

Àkọlé fídíò, Woli Kasali: Angẹli mi ni orékelẹ́wà Dọlapo Awoṣika
Published

'Mo fẹran Bunmi iyawo mi dáadáa'.

Woli Kasali ṣalaye fun BBC Yorùbá pe oun n fi orin fuji ati High life ti oun n kọ fi jere ọkan fun Oluwa ni.

O ni ohunkohun to ba wu onikaluku lo le fi jeere ọkan fun Kristi.

Bakan naa lo mẹnuba ipa angẹli ti Dolapo Awosika n ko laye oun.

Arole Orimọlade kinni ni oun ṣi n bẹ Dolapo pe ko gba lati jẹ iyawo lọọdẹ oun niṣu-lọka ni.

Koda, Woli Kasali ni gbogbo ayé lo maa ba oun ṣe idana Dọlapọ nigba ti ọrọ ba wọ tan.

Ni afikun, Wolii Kasali ṣalaye kikun lori ahesọ to n ja kiri pẹ oogun loun fi de Dolapọ mọlẹ.

O ni ko ṣeeṣe ki a fẹran oloju kan bọ Ifa ati pe ọmọ agba ni Dolapo fun ra rẹ.