Yoruba language: Àmì ohùn ṣe pàtàkì nínú èdè Yorùbá
Published
Kò sí ohun tó le tí kìí rọ- imọran agba.
Ede olóhùn ni ede Yoruba jẹ. Ami ohun lo maa n fi iyatọ ọrọ han ninu ede Yoruba.
BBC Yoruba ko fẹ ki ede yii parun ni a ṣe jade lọ beere itumọ gbolohun yii ati ami ori rẹ lọwọ awọn eniyan.
Adun lo n gbẹyin ewuro!
- Àjọ tó n rí si ọ̀rọ̀ fásitì (NUC) kéde ayédèrú Ọjọ̀gbọ́n tó tó ọgọ́rùn ún
- A ó kàn sí mọ̀lẹ́bí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kú létí ná kí a tó kéde orúkọ wọn-Iléeṣẹ́ Ọgbà ẹ̀wọ̀n
- Òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì, ọmọ ọdún 71 wọ gbaga ọlọ́pàá fún pípe iléeṣẹ́ kan fún ìgbà 24, 000
- Bàbá mi fún mi ní kíndìnrín rẹ̀ láti dóòlà ẹ̀mí mi- Sam
Adun lo n gbẹyin ewuro jẹ gbolohun iwuri ti a fi n parọwa fun ẹni to n la iṣoro kan tabi omii kọja pe ko ni suuru nitori ọpẹ lo maa gbẹyin ọrọ naa.
Ewuro koro ṣugbọn adun lo maa n gbẹyin rẹ ti eeyan ba jẹẹ lo ṣokunfa bi wọn ṣe n fi rọ eniyan lati tẹsiwaju lasiko ipenija.
Yoruba gbagbọ pe ki ẹni ti eegun n le ko maa rọju, nitori pe bo ṣe n rẹ ara aye naa lo n rẹ ara ọrun.
Idahun si ibeere ami gbolohun yii ni:
Adun lo n gbẹyin ewuro: re do mi mi do re mi re