Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó lọ kó ọjà ọlajà ní Shoprite Ilorin
Published
Bayii ni ọwọ awọn oṣiṣẹ alaabo sẹ tẹ awọn eeyan kan to lọ n ko ọja ninu awọn ṣọọbu to wa ni ile itaja igbalode Shoprite ati awọn ṣọọbu miran nibẹ.
Eyi waye ni owurọ ọjọ Satide, nibi ti awọn alaabo ti ka wọn mọ ibẹ.
Ọjọ Ẹti ni iroyin gbode pe awọn janduku fọ awọn ṣọọbu to wa ni ile itaja igbalode naa, ti wọn si ko awọn ọja to wa nibẹ lọ. Ṣugbọn ọwọ tẹ awọn kan to tun lọ sibẹ ni owurọ ọjọ Satide, lati lọ ko awọn nkan to ku sibẹ.
Ọkan lara awọn oniṣowo to ni ṣọọbu sibẹ sọ pe gbogbo foonu ti oun n ta ninu ṣọọbu oun, to fi mọ awọn eroja inu ile bi firiji, ni wọn tun ko lọ.